Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Hakeem OLAWALE

Designation: Lecturer I
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Eré-Onítàn Ìṣèlú Onírèké Ògè Gẹ́gẹ́ Bíi Ọ̀nà Ìṣàfihàn Àléébù, Atọ́kùn Ìpèníjà Àti Ọ̀nà Àbáyọ Fún Ìṣèjọba Nàìjíríà

Bí ètò òṣèlú àwùjọ tàbí orílẹ̀-èdè kan bá fẹ́ fẹsẹ̀ rinlẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú tó jíire, ó ta , ó sì ṣe pàtàkì kí àwọn ènìyàn fúra wọn finú-fíndọ̀ gbìyànjú láti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú igbọ́ra-ẹni-yé nípa ṣíṣe àtúntò láti rí ojútùú sí àwọn nǹkan tó bàjẹ́ nítorí pé kò sí ohun tó bàjẹ́ kọjá àtúnṣe. Nípa ṣíṣe èyí, ìdàgbàsókè tó gbọn-n-gbọ́n lè wáyé, àwọn orílẹ̀-èdè náà yóò sì lè fakọyọ bí ètò ìṣèlú orílẹ̀-èdè mìíràn ní àgbáyé. Onírúurú àìṣedéédé bí ìwà kòtọ́; ìlù bámúbámú la yó láàrin àwọn atàlú-ṣòwò; ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà òun ẹ̀sìn láwùjọ; àisí òmìnira láti yan sí ib tó wuni; ṣíṣe àfọwọ́rá ohun tó yẹ kí mùtúmùwà gbádùn, èyí tó mú kí ọmọ ẹlẹ́ran máa ti eegun jẹ; títa ogún àjọni àti gbígbé ẹni tí kò lè to ọ̀dẹ̀dẹ̀ lásán sípò adarí láti máa ṣe àkóso lé àwọn ènìyàn lórí ó fa rírákòrò oílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn òmìnira kó tó di ojúlówó ìnira. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètè àtúnṣe ń wáyé níwọ̀nba, síbẹ̀ a kò ṣàìrí àwọn ènìyàn tó kọtí ọ̀gbọn-in sí ìdẹ̀rùn àti ìṣàkóso orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìwé onítàn Ìsèlú Onírèké Ògè ṣe àfihàn àwòjíji ètò-ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bó ṣe hànde káàkiri àwùjọ kọ̀ọ̀kan, oríṣìíríṣìí àléébù tó máa ń wáyé nínú ètò ìṣèlú, àwọn ìpèníjà tó ń wáyé lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan pẹ̀lú ọ̀nà àbáyọ tí àwọn ènìyàn fi lè jàjàbọ́ kúrò lóko ìmúnisìn. Síwájú sí i, eré onítàn yìí jẹ́ kí a mọ̀ pé kíkáwọ́ gbera kò lè mú èso rere jáde nítorí pé àwọn olóṣèlú ti sọ ara wọn di ọmọláńgidi àwòrán àwòjátọ́, tí àlàbọrùn wọn tì dẹ̀wù fún orílẹ̀-èdè tí a kò sì fura. Ọ̀nànàbayọ tó tún fara hàn nínú ìwé Ìṣèlú Onírèké Ògè ni kí àwọn ènìyàn àwùjọ jí gìrì pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti gba ara wọn sílẹ̀ lóko ẹrú, kí wọ́n sì lè rìn jìnnà sí oko ìparun tí àwọn ọ̀jẹ̀lú ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí lọ kí àyípadà rere lè wà àti kí ìgbé-ayé ìrọ̀rùn lè bá tonílé-tàlejò. Nínú àyẹ̀wò iṣẹ́ yìí, ṣíṣe àmúlò tíọ́rì ajẹmóṣèlú jẹ́ kàn-án-ń-pá fún àtúpalẹ̀ ìwé eré onítàn yìí láti lè jẹ́ kí a rí òkodoro oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ìjìjàgbara máa ń gbà wáyé àti ìgbésẹ̀ àwọn mẹ̀kúnnù láti gba ara wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn olùjẹ́gàba olóṣèlú.
Total Publications : 9