My Publications | ||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|
S/N | Title | Abstract | Authors | Volume Numbers | Publication Type | Publication Date | Link | |
1 | Ojú Àmúwayé Yorùbá Nípa Obìnrin Nínú Orin Sẹnwẹlẹ Ìlọrin |
Ọ̀kan lára orin ìbílẹ̀ tó gbajúmọ̀ ní Ìlọrin ni orin sẹnwẹlẹ jẹ́. Àkóónú orin yìí kún fún ìkìlọ̀ ìwà, ẹ̀fẹ̀, ìpàkíyèsí, ìpanilẹ́rìn-ín, ọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìṣesí obìnrin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nínú iṣẹ́ yìí, a ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn orin sẹnwẹlẹ Alhaja Àwáwù Ìyáládùkẹ́ àti ti Múkáílà Ẹṣínrógunjó. Àfojúsùn wa ni láti wo àwọn àbùdá-àdámọ́ onírúurú tí obìnrin ní. Iṣẹ́ yìí túdìí ọ̀pọ̀ òkodoro nípa obìnrin bí wọ́n ṣe jẹ́ pàtàkì tó nínú àwùjọ àti kòṣeémání gẹ́gẹ́ bí iyọ̀ nínú ọbẹ̀ kó tó lè dùn. Ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ bí ìwà ìbàjẹ́ kò ṣe jẹ́ nǹkan pàtàkì lójú irúfẹ́ àwọn obìnrin kan. Ìlànà ìwádìí ni gbígbọ́ àwọn orin ìbílẹ̀ sẹnwẹlẹ Ìyáládùkẹ́ lóríṣiríṣi àti ti Múkáílà Ẹṣínrógunjó. A ṣe àdàkọ wọn láti lè ṣe ọ̀rínkínniwín àtúpalẹ̀ àwọn kókó ajẹmóbìnrin inú wọn. A tún ṣe àmúlò àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ tó wúlò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí. Tíọ́rì Ìmọ̀-Ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ ni a lò láti ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí nítorí pé ìbágbépọ̀ ẹ̀dá láàrin àwùjọ ló ń bí orin kíkọ. Àbájáde iṣẹ́ yìí fi hàn pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀bẹ olójú-méjì ni àwọn obìnrin; iyẹn ni pé bí abiyamọ gidi obìnrin rere ṣe wà, tí wọ́n níwà ìtìjú, àfaradà, ìtẹpámọ́ṣẹ́, ìdáàbò bo ọkọ àti ọmọ náà ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn jẹ́ oníwà-ìbàjẹ́ obìnrin, tí wọn kò léèpo lójú, alágbèrè, orogún ṣíṣe, olè jíjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ yìí fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ pé àwọn apohùn kò kùnà láti ṣe àfihàn àwọn obìnrin rere kí àwọn obìnrin akẹgbẹ́ wọn lè rí àwòkọ́ṣe rere lára wọn. Bákan náà ni wọn kò kùnà láti pàtẹ àwọn ìwà tí kò bójúmu tí àwọn obìnrin mìíràn ń hù nínú àwùujọ. A ṣe àkíyèsí pé, wọ́n ń ṣe àfihàn àwọn ìwà yìí láti fi kọ́ àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí abetí dídi nínú wọn lọ́gbọ́n ni. | Hakeem Ọláwálé | Vol. 31, | Journal | 2022-04-02 |