Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Hakeem OLAWALE

Designation: Lecturer I
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Ipa Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ Ìgbàlódé Lórí Ìdàgbàsókè Orin Ìbílẹ̀ Ọlọ́mọ-Ọba Ìlọrin

Ọ̀kan pàtàkì lára orin ìbílẹ̀ Ìlọrin tó jẹ́ ajẹmábo-jẹ-máàfin ni orin Ọlọ́mọ-Ọba Ìlọrin jẹ́. A tilẹ̀ tún lè pè é ní ajẹmágbà nítorí pé àwọn àgbàlagbà obìnrin tó jẹ́ ẹbí àti ìyàwó ní ìdílé ọba Ìlọrin ló máa ń kọ ọ́. Lóòótọ́, a kò lè ṣàfẹ́kù ìkópa àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ adélébọ̀ náà níbẹ̀ látì máa fojú sí i àti láti gbe orin náà, ṣùgbọ́n àwọn àgbàlagbà obìnrin tí ọjọ́ orí wọn ti lé ní ọgọ́ta ọdún ló wọ́pọ̀ nínú kíkọ orin náà. Àwọn tó jẹ́ ẹbí ọba Ìlọrin nìkan ni wọ́n ni orin yìí tí wọ́n sì fi máa ń yẹ́ ara wọn sí pàápàá jùlọ tí ọmọ ọba Ìlọrin kan bá ń ṣe ìgbéyàwó, yálà ó jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. A ṣàkíyèsí pé iṣẹ́ ìwádìí kò fi bẹ́ẹ̀ sí lórí orin yìí nítori pé wọn kìí gba àjòjì láàyè láti kópa níbẹ̀ débi tí yóò farabalẹ̀ máa ká eré wọn sílẹ̀. Èyí ló mú wa lọ gba ìyọ̀ǹda lati ààfin Ọba Ìlọrin gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́-ìwádìí, tí ó sì fún wa ní àǹfààní láti bá wọn kópa níbi òde orin wọn àti ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó kún. A ká wọn sínú ẹ̀rọ, a ya fọ́tò wọn, a sì tún rí orin wọn tó wà nínú fọ́nran díẹ̀ lára ìgbéyàwó tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ gbà láti ṣe àdàkọ fún ìtúpalẹ̀. Kókó pàtàkì tí iṣẹ́ yìí gùnlé ni àgbéyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń fi orin ólọ́mọ-ọba yìí jẹ́ láwùjọ Ìlọrin pẹ̀lú ipa pàtàkì tí onírúurú ọ̀nà ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ àti ti tọ́rọ́-fọ́n-kálé òde-òní ń kó lórí ìdàgbàsókè rẹ̀.Tíọ́rì Ajẹmọ́-àṣà-ìbílẹ̀ àti tíọ́rì Ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ ni a fi ṣàtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí. Àbájáde iṣẹ́ yìí tànmọ́lẹ̀ sí i bó ṣe ṣe pàtàkì tó kí a máa mú ìgbélárugẹ bá àwọn nǹkan àṣà ìbílẹ̀ wa gbogbo nípasẹ̀ ìṣàmúlò àwọn ohun èlò ìgbàlódé oríṣìíríṣìí kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan àjogúnbá wa má baà dohun ìgbàgbé, kí àmúgbòòrò àtí ìtẹ̀síwájú lè máa bá wọn, kó sì tún wúlò fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Kókó Ọ̀rọ̀: Ajẹmábo-jẹ-máàfin, Orin Ìbílẹ̀, Ọlọ́mọ-Ọba-Ìlọrin, Ajẹmágbà, Ìgbéyàwó
Total Publications : 9