My Publications | ||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|
S/N | Title | Abstract | Authors | Volume Numbers | Publication Type | Publication Date | Link | |
1 | Ìjẹyọ Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀, Èdè, Àṣà àti Ìtàn Pàtàkì Nínú Àṣàyàn Orin Ìbílẹ̀ Ìlọrin. |
Onírúurú ẹ̀ka ló máa ń ṣodo sínú orin ìbílẹ̀ nítorí pé inú àwùjọ ni àwọn akọrin ń gbé tí wọ́n sì máa ń ṣàmúlò láti inú ibú ìmọ̀ wọn, ìrírí wọ àti àrọ́bá láti ẹnu àwọn babańlá wọn, èyí tí wan máa ń sọ di orin láti fi èrò ọkàn wọn hàn àti fún ìdárayá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọrin ìbílẹ̀ ló gbọ́ èdè Yorùbá tó sì máa ń hàn nínú ìpohùn orin wọn. Ìjìnlẹ̀ èdè, àṣà ìbílẹ̀, ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́ àti òkodoro àwọn ìtàn mìíràn tó farasin máa ń dàwárí nínú orin wọ̀nyìí tí a bá gba wọn láìwo ti adùn orin nìkan. Orin tún máa ń ṣàfihàn ìwọ́ká ìran àwọn ènìyàn, pàápàá orírun wọn gan-an. Iṣẹ́ yìí ṣe àtúpalẹ̀ àyọlò àṣàyàn orin ìbílẹ̀ Yorùbá Ìlọrin bíi dàdàkúàdà, orin agbè, orin bàlúù, orin àlùgétà/bẹ̀ǹbẹ́, sẹnwẹlẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tíọ́rì tí a lò fún àtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí ni Tíọ́rì Ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-wò. Ìlànà tí a lò ni fífi ọ̀rọ̀ wá àṣàyàn díẹ̀ lára akọrin ìbílẹ̀ Ìlọrin lẹ́nu wò; àdàkọ orin wọn láti inú fọ́nrán àti àtúpalẹ̀ kókó tó jẹmọ́ èdè, àṣà àti ìtàn níbẹ̀. Iṣẹ̀ yìí ṣàfihàn pé tí ìtẹpẹlẹmọ́ àti ìpolongo bá wà fún gbígbọ́ àwọn orin ìbílẹ̀, ìlọsíwájú yóò máa bá èdè Yorùbá, tí àwọn èwe wa kò sì ní lè tẹ̀rì pátápátá sínú àwọn orin ìgbàlódé tàkasúfèé tó gbòde kan ní ọ̀rúndún yìí. Kókó Ọ̀rọ̀: Ibú Ìmọ̀, Àrọ́bá, Ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́, Orírun, Fọ́nrán. | Hakeem Olawale | Vol. 9, No. 3 | journal | 2019-02-05 |