My Publications | ||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|
S/N | Title | Abstract | Authors | Volume Numbers | Publication Type | Publication Date | Link | |
1 | ÌFÌWÁDÌÍSỌTUMỌ́ ÌYÁNRỌ̀FẸ́RẸ́ INÚ ORÍKÌ ORÍLẸ́ AWỌN ÌLÚ AJÓRÚKỌMỌ́-IFỌ́ |
Àṣamọ̀ Ohun tí isẹ́ ìwádìí dálé lórí ni àgbéyẹ̀wò àwọn ìyánrọ̀féé tó jẹ jáde nínú oríkì orílẹ̀ ìran Olúfọ́n ní àwọn ìlú ajórúkọmọ́-Ifọ́n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta – Ifọ́n Òròlú, Ìfọ́n Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí àti Ifọ́n Òmimà. Oríkì orílẹ̀ Olúfọ́n ti a gbà láti ẹnu àwọn abẹ́nà-ìmọ̀, èyí tí a ṣe àdàkọ rẹ̀ láti inú fọ́nrán, inú ìwé àti òríṣìí àkọọ́lẹ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni a ṣàmúlò fún iṣẹ́ yìí. Àwọn Ifọ́n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí wà ní agbègbè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nilẹ̀ Yorùbá tó jẹ́ pé sábàbí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣí kóówá wọn nídìí tí wọ̀n fi wà níbi tí wọ̀n wà lónìi. Aládìíkún, Ọláòṣà tó jẹ́ ọmọ Ọbàtálá sì ni baba gbogbo wọn. Iṣẹ́ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìyánròféré tó fara hàn nínú oríkì orílẹ̀ àwọn ìran Olúfọ́n. Iṣẹ́ yìí tún ṣàlàyé ní ọ̀rínkinníwín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀, gbólóhùn tàbí ìpèdè tí ìtumọ̀ wọn farasin tó sì nílò ìwádìí ìjìnlẹ̀ láti túdìí òkodoro nípa wọn. Tíọ́rì ìfìwádìsọ̀tumọ̀ (Hermeneutics) àti tíọ́rì ìmútànsọ (Narratology) ni a lò láti ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ náà. Iṣẹ́ yìí tún jẹ́ kí a mọ̀ pàtàkì oríkì-orílẹ̀ síi gẹ́gẹ́ bí okùnfà ìdára-ẹni-mọ̀; ó tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀pọ̀ nǹkan tó farasin nípa ìranOlúfọ́n àti pàtàkì wọn. Ó ṣàfihà ipa tí adé ń kó nínú ìṣèlú nílẹ̀ Yorùbá pàápàá láti ìgbà ìwáṣẹ̀. Ó fìdí agbára àti pàtàkì ìṣẹ̀ṣe hàn. A sì tún rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèwọ̀ àti orò ìdílé ló máa ń ní ìdí abájọ tó ṣokùnfà wọn. Iṣẹ́ yìí wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sí i wí pé àká ọgbọ́n tí ọwọ́ kílàǹkó rẹ̀ kò ṣe é yọ níbú àwo ni ìpohùn Yorùbá jẹ́ pàápàá jùlọ oríkì orílẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó sodo sín;u rẹ̀. Iṣẹ́ ìfiwádìísọ̀tumọ̀ sì máa ń túdìí òkodoro nípa àwọn ọ̀rọ̀, ìpèdè tàbí àṣamọ̀ tó bá farasin nínú afọ̀ yòówù-ó-jẹ́, tí yóò sì tànmọ́lẹ̀ sí i kedere láti lè ní òye ìjìnlẹ̀ ìtumọ̀ wọn. Kókó-ọ̀rọ̀: Ìfiwádìísọ̀tumọ̀, Ìyánrọ̀féé, Oríkì-orílẹ̀, Abẹ́nà-ìmọ̀, Ìmútànsọ | Ọláwálé, H. and Aransi, A. O. | Vol. 1, No. 2 | journal | 2020-12-01 |