Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Ayoola ARANSI

Designation: Senior Lecturer
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Ìlò Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ Ìgbàlódé Fún Ìpolongo Òògùn Ìbílẹ̀ Yorùbá

Àṣamọ̀ Ohun tó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ṣíṣe àfihàn ọ̀nà tí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ ń gbà láti ṣe ìpolongo ara wọn pẹ̀lú òògùn ti wọ́n ṣe fún àwọn ènìyàn nínú àwùjọ fún ìmúláradá , ìtọ́jú àti ìdènà àrùn. A ṣe àfihàn ìlànà ìpoloówó òògùn láyé àtijọ́ àti òde-òní èyí tó fún wa láyè láti jẹ́ kí a mọ ìyàtọ̀ àti ìjọra tówà nínú méjèèjì. A wo ìlànà tí wọ́n gbà ṣe ìkọ̀ọ̀kan wọn láti baà le fi hàn pé bí ìlànà ìgbàlódé ṣe dára tó náà ni àbùkù ṣe wà níbẹ̀. ọ̀nà tí a gbà ṣe ìwádìí ni pé , a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ ti a yàn láàyò pẹ̀lú àwọn alárenà ètò ìpàtẹ òògùn ní ilé-iṣẹ́ rédíò àti tẹlifisàn lẹ́nu wò. A ṣe ìwádìí nípa iṣẹ́ òògùn wọn , bátànì tí wọn \n lò láti tajà wọn. Ibi tí wọ́n ti ń ṣe òògùn wọn àti ibi tí a ti lè rí wọn rà. Iṣẹ́ yìí jẹ́ kí a mọ̀ pé ìlò ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé ń polongo iṣẹ́ ìṣègùnn àwọn Yorùbá fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Yorùbá. Ó tún jẹ́ kí a mọ̀ pé òògùn ìbílẹ̀ Yorùbá tayọ àwùjọ Yorùbá nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí kì í ṣe ọmọ Yorùbá ló ní àǹfààní láti gbọ́ ìpolówó òògùn wọn. Síwájú sí i, ìlò ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé tún jẹ́ kí òògùn Yorùbá jẹ́ ìlú mọ̀-ọ́n-ká. Yàtọ̀ sí èyí, ó jẹ́ kí a mọ̀ pé àwọn òògùn ẹ̀yà mìíràn tún ń jẹyọ nínú ọgbọ́n ìṣègùn ẹ̀yà Yorùbá. Ìpolowówó òògùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé jẹ́ kí òògùn ìbílẹ̀ Yorùbá gbòòrò sí i, èyí sì jẹ́ orísun ìdàgbàsókè iṣẹ́ abínibí ìran Yorùbá. Kókó Ọ̀rọ̀: Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀, Òògùn Ìbílẹ̀, Ìpolongo, Yorùbá
Total Publications : 17