Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Ridwan Rabiu

Designation: Assistant Lecturer
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Agbeyewo Akoonu Awon Tiori Fonoloji ni Ede Yoruba

Àṣamọ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àlàyé lẹ́kùn-ún lórí àkóónú tíọ́rí fonọ́lọ́jì mẹ́ta ní èdè Yorùbá. Àwọn tíọ́rì náà ni tíọ́rì Onídàrọ (Generative Phonology), tíọ́rì Adápelení (Auto-segmental Phonology) àti tíọ́rì Olùborí akópa (Optimality theory). Àfojúsùn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣàlàyé àwọn tíọ́rì yií ní èdè Yorùbá, èyí tí yóó túbọ̀ jẹ́ kó rọrùn si fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá tí wọn nílò àwọn tíọ́rì yìí fún ìtúpalẹ̀, pàápàá jùlọ nínú iṣẹ́ àkànṣe wọn. Èyí ríbẹ́ẹ̀ níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé bàtà ò sí òde ò yá ni tíọ́rì jẹ́ fún iṣẹ́ ìwádìí ajẹmédè. Iṣẹ́ ìwádìí yìí gùnlé iṣẹ́ àwọn onímọ̀ ìsáájú bí i Chomsky ati Halle (1968), Goldsmith (1978), Prince àti Smolensky (1991) abbl. Díẹ̀ lára ohun tí a rí fàyọ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé àlàyé lórí àwọn òfin fonọ́lọ́jì tí ó ń ṣiṣẹ́ afárá láàárín ìhun ìpìlẹ̀ àti ìhun òkè afọ̀ ni tíọ́rì onídàrọ fúnka mọ. Bákan náà àlàyé lórí òmìnira àmì ohùn gẹ́gẹ́ bí ègé tí ó lè dádúró láì fi ti ègé ìró ṣe ni kókó ohun tí tíọ́rì adápelení fúnka mọ́. Àlàyé wa lórí tíọ́rì olúborí akópa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé agbára òté (constraint) àti òǹfà ìsopọ̀ (Eval) lórí síṣẹ̀dá afọ̀ aṣeégbà ni kókó èrò tíọ́rì adápelení. Ní ìkádìí, a rọ àwọn onímọ̀ èdè láti tubọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ títú àwọn tíọ́rì ajẹmédè palẹ̀ sí èdè Yorùbá láti mú kí kíkọ́ èdè Yorùbá pẹ̀lú ìtúpalẹ̀ àwọn èròjà àmúkalẹ̀ fáyẹ̀wò pẹ̀lú àwọn tíọ́rì fonolọ́jì yìí rọrùn fún àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá. Kọ́kọ́ Ọ̀rọ̀-, Tíọ́rì, Onídàrọ, Adápelení, Olúborí-Akópá, Òté, Afárá-Ìsopọ̀
Total Publications : 3