Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Ridwan Rabiu

Designation: Assistant Lecturer
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Atunyewo Oro-Asopo Gege Bi Isori Oro Ninu Ede Yoruba

Àṣamọ̀ Kókó ohun tí a gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni àtúngbéyẹ̀wò awuyewuye tí ó ń súyọ lórí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá. Orísun awuyewuye yìí ni àìkò ẹnu àwọn onímọ̀ gírámà èdè Yorùbá lórí iye ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó wà nínú èdè náà. A ṣe ìgbéléwọ̀n iṣẹ́ yìí pẹ̀lú èrò àwọn onímọ̀ ìṣáájú lórí ipò tí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ wà nínú èdè Yorùbá, ṣé ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ ni tàbí iṣẹ́ lásán? Ọgbọ́n ìwádìí tí a lò ní í ṣe pẹ̀lú àgbéyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn lórí iye ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Iṣẹ́ ìwádìí yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ àsopọ̀ nínú èdè Yorùbá tako èrò àwọn onímọ̀ bí i Yusuf (1999), Ajiboye (2011) àti Adékẹ́yè (2002, 2012 àti 2016) pé ìsọ̀rí iṣẹ́ lásán ni ọ̀rọ̀-àsopọ̀ nínú èdè Yorùbá. Lára àwọn àbùdá tí a rí fàyọ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí tí ó gbe èrò wa lẹ́sẹ̀ pé ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ ni ọ̀rọ̀-àsopọ̀ ni pé àbùdá fonọ́lọ́jì rẹ̀ fihàn pé àmì ohùn ìsàlẹ̀ ni ó máa ń bẹ̀rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀-àsopọ̀ tó wà nínú èdè Yorùbá. Àbùdá mọfọ́lọ́jì ọ̀rọ̀ àsopọ̀ tí ó yà á sọ́tọ́ sí àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó kù ni pé mọ́fíìmù ìpìlẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ àsopọ̀ tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Ní ti abala síńtaàsì, agbedeméjì ìhun tí a fẹ́ sopọ̀ yálà ó jẹ́ ẹ̀yọ ọ̀rọ̀, àpólà tàbí odidi gbólóhùn ni ọ̀rọ̀ àsopọ̀ máa ń wà. Ní ìkádìí, èrò wa ni pé iṣẹ́ ìwádìí yìí ti yanjú awuyewuye tí ó wà lórí ọ̀kan nínú àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó wà nínú èdè Yorùbá èyí tíí ṣe ọ̀rọ̀-àsopọ̀. Kókó Ọ̀rọ̀- Ọ̀rọ̀-Àsopọ̀, Ìsọ̀rí-Iṣẹ́, Ìsọ̀rí-Ọ̀rọ̀, Yorùbá, Òfin-Ìsopọ̀
Total Publications : 3