Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Ridwan Rabiu

Designation: Assistant Lecturer
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Atungbeyewo Igbese Iyopo Faweli Ninu Ede Yoruba: Eri lati Inu Oruko Ajemo Ibi ati Eni

Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ojú ọ̀tun wo iyọ́pọ̀ fáwẹ̀lì gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì nínú èdè Yorùbá. Èróńgbà iṣé ìwádìí yìí ni láti lo ẹ̀rí láti inú àwọn orúkọ ajẹmọ́ ibi àti orúkọ ajẹmọ́ ẹni fi ìdí ìjẹyọ ìyọ́pọ̀ fáwẹ̀lì pẹ̀lú ọ̀nà tí ó ń gbà wáyé nínú èdè Yorùbá múlẹ̀. Ọ̀nà méjì ni a gbà ṣàkójọ àwọn èròjà àmúkalẹ̀ fáyẹ̀wò wa: láti inú iṣẹ́ àwọn onímọ̀ ìṣáájú àti àgbàsílẹ̀ àwọn wúnrẹ̀n ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn abẹ́nà ìmọ̀ wa. Tíọ́rí tí a ṣàmúlò fún ìtúpalẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni tíọ́rì onídàrọ èyí ti Chomsky àti Halle (1968) ṣe agbátẹrù rẹ̀. Kókó ohun tí a rí fàyọ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ìyọ́pọ̀ fáwẹ̀lì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì inú èdè Yorùbá, tí ìjẹyọ rẹ̀ sì fi ojú hànde nínú ìṣẹ̀dá àwọn orúkọ ajẹmọ́ ibi bí i ‘Eréko’, ‘Akèètàn’ àti ‘Ògbómọ̀ṣọ́’. Ìjẹyọ ìyọ́pọ̀ fáwẹ̀lì tún fi ojú hàn nínú ìṣẹ̀dá àwọn orúkọ ajẹmọ́ ẹni bí i ‘Adénúgà’, ‘Awónúgà’, ‘Awónúsì’, ‘Oyènúsì’, ‘Ọmọ́ruyì’ abbl. Ní ìkádìí, a rọ àwọn aṣèwádìí nínú ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè láti túbọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ fífi ìmọ̀ fonọ́lọ́jì àti àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè tó kù bí i mọfọ́lọ́jì, síńtáàsí, sẹ̀máńtiìkì abbl.ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn orúkọ Yorùbá nítorí ọ̀pọ̀ ohun tí ó farasin nínú èdè ni irú iṣẹ́ ìwádìí bẹ́ẹ̀ le tú síta. Kókó Ọ̀rọ̀-Fonọ́lọ́jì, Ìgbésẹ̀ fonọ́lọ.jì, Tíọ́rì Onídàrọ, Fáwẹ̀lì Àmúwọlé, Fáwẹ̀lì Àmújáde
Total Publications : 3