Over 0 Teaching & Non Teaching Staff!

Kwara State University

Samson Tella

Designation: Assistant Lecturer
Department: Linguistics African and European Languages
My Publications
S/N Title Abstract Authors Volume Numbers Publication Type Publication Date Link
1

Ọ̀rọ̀-ìṣe ''kú'' nínú Ìkínni Yorùbá

Àsamọ̀ Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀-ìṣe ló wà ní èdè Yorùbá. Àbùdá, ibi ijẹyọ, ìlò àti ìtumọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wà lọ́wọ́ sàkáání tí wọ́n ti jẹ yọ. Nínú iṣẹ́ yìí, a ó wo èrò àwọn onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀-ìṣe kú bí ó ti jẹ yọ nínú ìkíni Yorùbá, a ó sì se àwílé tiwa kí á tó se ìgbéléwọ̀n ọ̀rọ̀-ìṣe yìí. A sàkíyèsí pé ojúlówó ọ̀rọ̀-ìṣe ni kú pẹ̀lú àbùdá àdámọ́ ibi ìjẹyọ tó sàrà ọ̀tọ̀. A tún sàkíyèsí pé àkọpọ ọ̀rọ̀-arọ́pọ̀ orúkọ ẹnìkejì ẹyọ ẹ àti ọ̀rọ̀-ìṣe kú kìí se ẹkú ní ìbámu pẹ̀lú èrò Awobuluyi (2013). A tún sàkíyèsí ní ìbámu pẹ̀lú èrò àwọn onímọ́ pé ẹ̀dà ọ̀rọ̀-ìṣe kú ni ọ̀rọ̀-ìṣe kí nítorí pé ibi tí kí ti jẹ yọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kú kò lè jẹ yọ̀. Ìdí nìyí tí àwa fi pè kú ní Ọ̀rọ̀-ìṣe Onítumọ̀-Àkànlò kí. Kókó Ọ̀rọ̀: Ọ̀rọ̀-Ìṣe, Ìkíni Yorùbá, Ọ̀rọ̀-arọ́pọ̀ orúkọ, Àkànlò.
Total Publications : 3